Omo aja tikotilaju ao ko egbo tude lelori ninu ape ijogun tiyo bomole Dada aofi
atare odidi lelori ao Jo aolo kuna aomafi oti lo nigbakugba
OFORE; Alagadanla lórúko tí a npe ayé arabatasi lórúko tí a npe ilẹ, tí àbá fi ẹfun fún
ayé asaya gagati, tí àbá fi edidi di lẹ, ilé àrè pesupesu, tí àbá ṣepe sọ ogun, ará ogún
alè kókó, ọmọ wọn nílé ìfẹ ohùn lóbí atepe, tobajebee a jẹ wipe emi o untele yìí pẹ,
únjẹ́ ọmọde lóba ní kín máa tẹlé yìí péé, koku bi ajá ṣeun kú tountogboro, agbalagba
t'oba niki máa tẹlé yìí péé, koku bi àgùtàn ṣeun kú tóun ẹnu rẹ bolobolo, t'oba ṣepe
ẹyin ìyá mí aje, l'ẹba ní nki mọn tẹlẹ yìí péé koku bí Adiye òpìpì ṣeun kú tóun tí agada
orí rẹ, méjèjì, únjẹ́ ọmọde lóba ní kín mọn tẹlẹ yìí péé, óò náà ọtí ni kiwọn máa bá
rọrun, ọna òdì ẹyẹseye ofifi apá seye, ẹyẹ seye f'ẹsẹ seye, ẹyẹseye ofi ẹsẹ òsì fo igba
ọwọ alagbẹdẹ wòó, ewé wole alára ẹyẹ pàá ọmọ alára, ẹyẹ wole ajero ẹyẹ pàá ọmọ
ajero, ẹyẹ wọlé orangun ile ìlà wọn sọ wipe nibo ni awọn alawo tún kusi, wọn lọsí ilé
olórí ajangbo wewe tuse awo alára ẹyẹ pàá wọn, wọn lọ sí ilé bọnbọn laguntan unwo
tinse awo ilé ajero ẹyẹ p'awọn, wọn lọsí ilé afi koríko òkè tinse awo orangun ile ila
ọya kété ẹyẹ p'awọn, wọn gbéra lọsí ilé orunmila wọn ní abọru boye bàbá ooo, wọn ní
kí egbò keto, won ni awọn yio pàá óò, , awọn yio pàá ọmọ rẹ, awọn yio pàá àyà rẹ,
awọn yio pàá aboyún ilé rẹ ati alamoran ree, wipe awọn òsì ní jékí o ṣe àṣeyọrí,
orunmila wà dawon lohùn wipe, è kólé pàmi, ekole pàá ọmọ mí, ekole pàá àyà mí, bẹ
sini ekole pàá aboyún ilé mi, èmi náà yíò ṣiṣe àṣeyọrí, wọn ní báwo ní orunmila yíò ṣe
ṣe àṣeyọrí, orunmila péé òun mọn orukọ mẹtẹta tíì ẹyin àjé njẹ, awọn wà l'anu won,
wọn ní haahaa!!! Ase ẹni tin otun mọn orukọ awọn akoko orunmila ní ati inú soro ní
ìyá yín njẹ, òní atedo jokan ní orúkọ tí baba yín njẹ, orukọ ẹyin àjé òní ẹyin gangan ní
owala nkara, wọn ní òdàa náà ọrọ di ọrọ imule, òdì ọrọ eewọ, wọn ní kí orunmila ko
tọju ìgbín apinnu meji(2) koko sefun sefun lọwọ sí pẹlu ewé aluki, wọn ní kokootútù
opan náà lọwọ sí, wọn ní nitori wipe ohun ní odu tí àwọn tẹwa sile- ayé, wọn ní kí
wọn ofi búra fún orunmila wipe ẹnikẹni toba jee nínú ọbẹ yìí, wọn ní àwọn yíò máa
bọwọ rẹ, awọn yio máa yọnu sí èmi ọmọ Lagbaja.......modi ẹni ọwọ lat'oni lọ, nitori bí
erin baaje loko abowo aluki bi efòn baaje loko abowo aluki, àjé kàn kí gboju gboya
kobaa lórí Igi ajeobale, Oseewoo!! Òsá mèjí o wá lore bámi s'àwon wàá l'ọkunrin
l'obinrin lomode lagba, kí wọn o máa fún èmí ọmọ Lagbaja...... lọwọ è mí lati òní lọ.